I. Sam 21

21
Dafidi Sá fún Saulu
1DAFIDI si wá si Nobu sọdọ Ahimeleki alufa; Ahimeleki si bẹ̀ru lati pade Dafidi, o si wi fun u pe, Eha ti ri ti o fi ṣe iwọ nikan, ati ti kò si fi si ọkunrin kan ti o pẹlu rẹ?
2Dafidi si wi fun Ahimeleki alufa pe, ọba paṣẹ iṣẹ kan fun mi, o si wi fun mi pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ idi iṣẹ na ti mo rán ọ, ati eyi ti emi ti paṣẹ fun ọ; emi si yàn awọn iranṣẹ mi si ibi bayi.
3Njẹ kili o wà li ọwọ́ rẹ? fun mi ni ìṣu akara marun li ọwọ́ mi, tabi ohunkohun ti o ba ri.
4Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin.
5Dafidi si da alufa na lohùn, o si wi fun u pe, Nitotọ a ti pa ara wa mọ kuro lọdọ obinrin lati iwọn ijọ mẹta wá, ti emi ti jade; gbogbo nkan awọn ọmọkunrin na li o mọ́, ati akara na si wa dabi akara miran, ye e pãpã nigbati o jẹ pe omiran wà ti a yà si mimọ́ loni ninu ohun elo na.
6Bẹ̃ni alufa na si fi akara mimọ́ fun u; nitoriti kò si akara miran nibẹ bikoṣe akara ifihan ti a ti ko kuro niwaju Oluwa, lati fi akara gbigbona sibẹ li ọjọ ti a ko o kuro.
7Ọkunrin kan ninu awọn iranṣẹ Saulu si mbẹ nibẹ li ọjọ na, ti a ti da duro niwaju Oluwa; orukọ rẹ̀ si njẹ Doegi, ara Edomu olori ninu awọn darandaran Saulu.
8Dafidi si tun wi fun Ahimeleki pe, Kò si ọ̀kọ tabi idà lọwọ rẹ nihin? nitoriti emi kò mu idà mi, bẹ̃li emi kò mu nkan ijà mi lọwọ, nitoripe iṣẹ ọba na jẹ́ iṣẹ ikanju.
9Alufa na si wipe, idà Goliati ara Filistini ti iwọ pa li afonifoji Ela ni mbẹ, wõ, a fi aṣọ kan wé e lẹhin Efodu; bi iwọ o ba mu eyini, mu u; kò si si omiran nihin mọ bikoṣe ọkanna. Dafidi si wipe, Kò si eyiti o dabi rẹ̀, fun mi.
10Dafidi si dide, o si sa ni ijọ na niwaju Saulu, o si lọ sọdọ Akiṣi, ọba Gati.
11Awọn iranṣẹ Akiṣi si wi fun u pe, Ṣe eyiyi ni Dafidi ọba ilẹ na? nwọn kò ha ti da ti nwọn si gberin nitori rẹ̀ ni ijo, pe, Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbãrun tirẹ̀?
12Dafidi si pa ọ̀rọ wọnyi mọ li ọkàn rẹ̀, o si bẹ̀ru Akiṣi ọba Gati gidigidi.
13On si pa iṣe rẹ̀ dà niwaju wọn, o si sọ ara rẹ̀ di aṣiwere li ọwọ́ wọn, o si nfi ọwọ́ rẹ̀ há ilẹkun oju ọ̀na, o si nwà itọ́ si irungbọn rẹ̀.
14Nigbana ni Akiṣi wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ẹnyin ri pe ọkunrin na nhuwà aṣiwere; njẹ nitori kini ẹnyin ṣe mu u tọ̀ mi wá?
15Mo ha ni aṣiwere fi ṣe? ti ẹnyin fi mu eyi tọ̀ mi wá lati hu iwa aṣiwere niwaju mi? eleyi yio ha wọ inu ile mi?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 21: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀