I. Sam 2:22-36

I. Sam 2:22-36 YBCV

Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ. O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá. Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn. Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu. Ẹni Ọlọrun kan tọ Eli wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Gbangba ki emi fi ara hàn ile baba rẹ, nigbati nwọn mbẹ ni Egipti ninu ile Farao? Emi ko si yàn a kuro larin gbogbo ẹya Israeli lati jẹ alufa mi, lati rubọ lori pẹpẹ mi, lati fi turari jona, lati wọ efodi niwaju mi, emi si fi gbogbo ẹbọ ti ọmọ Israeli ima fi iná sun fun idile baba rẹ? Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra? Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi. Kiye si i, ọjọ wọnni mbọ̀, ti emi o ke iru rẹ kurò, ati iru baba rẹ, kì yio si arugbo kan ninu ile rẹ. Iwọ o ri wahala ti Agọ, ninu gbogbo ọlà ti Ọlọrun yio fi fun Israeli: kì yio si si arugbo kan ninu ile rẹ lailai. Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn. Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú. Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo. Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o ba kù ni ile rẹ yio wá tẹriba fun u nitori fadaka diẹ, ati nitori okele onjẹ, yio si wipe, Jọwọ fi mi sinu ọkan ninu iṣẹ awọn alufa, ki emi ki o le ma ri akara diẹ jẹ.