Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò le tọ Filistini yi lọ lati ba a jà: nitoripe ọdọmọde ni iwọ, on si jẹ jagunjagun lati igba ewe rẹ̀ wá. Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo. Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a. Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà. Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ. Saulu si fi gbogbo ihamọra ogun rẹ̀ wọ̀ Dafidi, o si fi ibori idẹ kan bò o li ori; o si fi ẹwu ti a fi irin adarọ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ.
Kà I. Sam 17
Feti si I. Sam 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 17:33-38
5 Days
King David is described in the New Testament as a man after God’s own heart, meaning that he aligned his own heart with that of God’s. As we study David’s life, our goal for this series is to analyze the things David did in 1 & 2 Samuel in order to mold our hearts after God’s and resemble the same intensity of focus and spirit that David showcased throughout his life.
6 Awọn ọjọ
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò