I. Sam 17:1-16

I. Sam 17:1-16 YBCV

AWỌN Filistini si gbá ogun wọn jọ si oju ijà, nwọn si gba ara wọn jọ si Ṣoko, ti iṣe ti Juda, nwọn si do si Ṣoko ati Aseka, ni Efesdammimi. Saulu ati awọn enia Israeli si gbá ara wọn jọ pọ̀, nwọn si do ni afonifoji Ela, nwọn si tẹ́ ogun de awọn Filistini. Awọn Filistini si duro lori oke kan li apa kan, Israeli si duro lori oke kan li apa keji: afonifoji kan sì wa larin wọn. Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan. On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ. On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀. Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀. O si duro o si kigbe si ogun Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin jade lati tẹgun? ṣe Filistini kan li emi iṣe? ẹnyin si jẹ ẹrú Saulu. Ẹnyin yan ọkunrin kan fun ara nyin, ki ẹnyin si jẹ ki o sọkale tọ̀ mi wá. Bi on ba le ba mi ja, ki o si pa mi, nigbana li awa o di ẹrú nyin: ṣugbọn bi emi ba le ṣẹgun rẹ̀, ti emi si pa a, nigbana ni ẹnyin a si di ẹrú wa, ẹnyin o si ma sìn wa. Filistini na si wipe, Emi fi ija lọ̀ ogun Israeli li oni: fi ọkunrin kan fun mi, ki awa mejeji jumọ ba ara wa jà. Nigbati Saulu ati gbogbo Israeli gbọ́ ọ̀rọ Filistini na, nwọn damu, ẹ̀ru nlanla si ba wọn. Dafidi si jẹ ọmọ ara Efrata na ti Betlehemu Juda, orukọ ẹniti ijẹ Jesse; o si ni ọmọ mẹjọ, o si jẹ arugbo larin enia li ọjọ Saulu. Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma. Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin. Ṣugbọn Dafidi lọ, o si yipada lẹhin Saulu, lati ma tọju agutan baba rẹ̀ ni Betlehemu. Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa