I. Sam 17:1-16

I. Sam 17:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN Filistini si gbá ogun wọn jọ si oju ijà, nwọn si gba ara wọn jọ si Ṣoko, ti iṣe ti Juda, nwọn si do si Ṣoko ati Aseka, ni Efesdammimi. Saulu ati awọn enia Israeli si gbá ara wọn jọ pọ̀, nwọn si do ni afonifoji Ela, nwọn si tẹ́ ogun de awọn Filistini. Awọn Filistini si duro lori oke kan li apa kan, Israeli si duro lori oke kan li apa keji: afonifoji kan sì wa larin wọn. Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan. On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ. On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀. Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀. O si duro o si kigbe si ogun Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin jade lati tẹgun? ṣe Filistini kan li emi iṣe? ẹnyin si jẹ ẹrú Saulu. Ẹnyin yan ọkunrin kan fun ara nyin, ki ẹnyin si jẹ ki o sọkale tọ̀ mi wá. Bi on ba le ba mi ja, ki o si pa mi, nigbana li awa o di ẹrú nyin: ṣugbọn bi emi ba le ṣẹgun rẹ̀, ti emi si pa a, nigbana ni ẹnyin a si di ẹrú wa, ẹnyin o si ma sìn wa. Filistini na si wipe, Emi fi ija lọ̀ ogun Israeli li oni: fi ọkunrin kan fun mi, ki awa mejeji jumọ ba ara wa jà. Nigbati Saulu ati gbogbo Israeli gbọ́ ọ̀rọ Filistini na, nwọn damu, ẹ̀ru nlanla si ba wọn. Dafidi si jẹ ọmọ ara Efrata na ti Betlehemu Juda, orukọ ẹniti ijẹ Jesse; o si ni ọmọ mẹjọ, o si jẹ arugbo larin enia li ọjọ Saulu. Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma. Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin. Ṣugbọn Dafidi lọ, o si yipada lẹhin Saulu, lati ma tọju agutan baba rẹ̀ ni Betlehemu. Filistini na a si ma sunmọ itosi li owurọ ati li alẹ, on si fi ara rẹ̀ han li ogoji ọjọ.

I. Sam 17:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka. Saulu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ibùdó tiwọn sí àfonífojì Ela, wọ́n sì múra ogun de àwọn ọmọ ogun Filistini. Àwọn Filistini dúró lórí òkè ní apá kan, àwọn Israẹli sì dúró lórí òkè ní apá keji. Àfonífojì kan sì wà láàrin wọn. Akikanju ọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Goliati, ará ìlú Gati, jáde wá láti ààrin àwọn Filistini. Ó ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹfa ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Ó dé àṣíborí bàbà, ó wọ ẹ̀wù tí wọ́n fi bàbà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) ṣekeli. Ó ní ihamọra bàbà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ọ̀kọ̀ bàbà kan sí èjìká rẹ̀. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dàbí igi òfì, irin tí ó wà lórí ọ̀kọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹta (600) òṣùnwọ̀n ṣekeli. Ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì ń rìn níwájú rẹ̀. Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà. Bí ó bá pa mí, a óo di ẹrú yín. Ṣugbọn bí mo bá ṣẹgun rẹ̀, tí mo sì pa á, ẹ óo di ẹrú wa. Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.” Nígbà tí Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Ọmọ Jese ni Dafidi, ará Efurati ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda; Ọmọkunrin mẹjọ ni Jese bí, ó sì ti di arúgbó nígbà tí Saulu jọba. Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta. Dafidi ni àbíkẹ́yìn patapata; àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹta náà sì wà ninu àwọn ọmọ ogun Saulu. Dafidi a máa lọ sí Bẹtilẹhẹmu nígbà gbogbo láti tọ́jú agbo ẹran baba rẹ̀. Odidi ogoji ọjọ́ ni Goliati fi pe àwọn ọmọ ogun Israẹli níjà ní àràárọ̀ ati ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́.

I. Sam 17:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Filistini kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Soko ti Juda. Wọ́n pàgọ́ sí Efesi-Damimu, láàrín Soko àti Aseka, Saulu àti àwọn ọmọ Israẹli wọ́n kò ara wọ́n jọ pọ̀, wọ́n sì pàgọ́ ní Àfonífojì Ela, wọ́n sì gbé ogun wọn sókè ní ọ̀nà láti pàdé àwọn Filistini. Àwọn Filistini sì wà ní orí òkè kan àwọn ọmọ Israẹli sì wà ní orí òkè mìíràn, àfonífojì sì wà láàrín wọn. Ọ̀gágun tí a ń pè ní Goliati, tí ó jẹ́ ará Gati, ó wá láti ibùdó Filistini. Ó ga ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìnà ìka kan ní ìbú. Ó ní àṣíborí idẹ ní orí rẹ̀, ó sì wọ ẹ̀wù tí a fi idẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọ̀n ẹ̀wù náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì idẹ (5,000). Òun sì wọ ìhámọ́ra idẹ sí ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àpáta idẹ kan láàrín ẹ̀yìn rẹ̀. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ rí bí apásá ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn (600) kílógírámù méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀. Goliati dìde, ó sì kígbe sí ogun Israẹli pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun? Ṣé èmi kì í ṣe Filistini ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Saulu? Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi. Tí òhun bá sì le jà tí ó sì pa mí, àwa yóò di ẹrú u yín, ṣùgbọ́n tí èmi bá lè ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ̀yin yóò di ẹrú u wa, ẹ̀yin yóò sì máa sìn wá.” Nígbà náà Filistini náà wí pé, “Èmi fi ìjà lọ ogun Israẹli ní òní! Ẹ mú ọkùnrin kan wá kí ẹ sì jẹ́ kí a bá ara wa jà.” Nígbà tí Saulu àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Filistini, ìdààmú bá wọn. Nísinsin yìí Dafidi jẹ́ ọmọ ará Efrata kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jese, tí ó wá láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda, Jese ní ọmọ mẹ́jọ, ní àsìkò Saulu ó ti darúgbó ẹni ọdún púpọ̀. Àwọn ọmọ Jese mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Saulu lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Eliabu: Èyí èkejì ni Abinadabu, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣamma. Dafidi ni ó kéré jù nínú wọn. Àwọn àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì tẹ̀lé Saulu, Ṣùgbọ́n Dafidi padà lẹ́yìn Saulu, láti máa tọ́jú àgùntàn baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu. Fún ogójì ọjọ́, Filistini wá síwájú ní àràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ wọ́n sì fi ara wọn hàn.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa