Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa.
On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi.
On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.
O si ṣe bi o ti mbẹbẹ sibẹ niwaju Oluwa, bẹ̃ni Eli kiyesi ẹnu rẹ̀.
Njẹ Hanna, on nsọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kiki etè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀: nitorina ni Eli fi rò pe, o mu ọti-waini yó.
Eli si wi fun u pe, Iwọ o ti mu ọti-waini pẹ to? mu ọti-waini rẹ kuro lọdọ rẹ.
Hanna si dahun wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin oniròbinujẹ ọkàn: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn ọkàn mi li emi ntú jade niwaju Oluwa.
Má ṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ irò ati ibinujẹ inu mi ni mo ti nsọ disisiyi.
Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ.
On si wipe, Ki iranṣẹbinrin rẹ ki o ri ore-ọfẹ loju rẹ. Bẹ̃li obinrin na ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, ko si fà oju ro mọ.
Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn wolẹ sìn niwaju Oluwa, nwọn pada wá si ile wọn si Rama: Elkana si mọ aya rẹ̀; Oluwa si ranti rẹ̀.
Nitorina, o si ṣe, nigbati ọjọ rẹ̀ pe lẹhin igbati Hanna loyun, o si bi ọmọkunrin kan, o si pe orukọ rẹ̀ ni Samueli, pe, Nitoriti mo bere rẹ̀ lọwọ Oluwa.
Ọkunrin na Elkana, ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀, goke lọ lati rubọ ọdun si Oluwa, ati lati san ileri ifẹ rẹ̀.
Ṣugbọn Hanna ko goke lọ; nitori ti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, o di igbati mo ba gba ọmu lẹnu ọmọ na, nigbana li emi o mu u lọ, ki on ki o le fi ara han niwaju Oluwa, ki o si ma gbe ibẹ titi lai.
Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi gba ọmu li ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ki Oluwa ki o sa mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ. Bẹ̃li obinrin na si joko, o si fi ọmu fun ọmọ rẹ̀ titi o fi gbà a lẹnu rẹ̀.
Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde.
Nwọn pa ẹgbọrọ malu, nwọn si mu ọmọ na tọ̀ Eli wá.
Hanna si wipe, oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro li ẹba ọdọ rẹ nihin ti ntọrọ lọdọ Oluwa.
Ọmọ yi ni mo ntọrọ; Oluwa si fi idahun ibere ti mo bere lọdọ rẹ̀ fun mi:
Nitorina pẹlu emi fi i fun Oluwa; ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀: nitoriti mo ti bere rẹ̀ fun Oluwa. Nwọn si wolẹ-sin Oluwa nibẹ.