NIGBANA ọkunrin kan wà, ara Ramataim-sofimu, li oke Efraimu, orukọ rẹ̀ ama jẹ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ara Efrata.
O si ni aya meji; orukọ ekini ama jẹ Hanna, orukọ ekeji a si ma jẹ Peninna: Peninna si bimọ, ṣugbọn Hanna kò bi.
Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ.
Nigbati o si di akoko ti Elkana ṣe irubọ, o fi ipin fun Peninna aya rẹ̀, ati fun gbogbo ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
Ṣugbọn Hanna li on fi ipin ẹni meji fun; nitori ti o fẹ Hanna: ṣugbọn Oluwa ti se e ni inu.
Orogún rẹ̀ pẹlu a si ma tọ́ ọ gidigidi lati mu u binu, nitoriti Oluwa ti se e ni inu.
Bi on iti ma ṣe bẹ̃ lọdọdun, nigbati Hanna ba goke lọ si ile Oluwa, bẹni Peninna ima bà a ni inu jẹ; nitorina ama sọkun, kò si jẹun.
Nigbana ni Elkana ọkọ rẹ̀ si sọ fun u pe, Hanna, ẽṣe ti iwọ nsọkun? ẽṣe ti iwọ kò si jẹun? ẽsi ti ṣe ti inu rẹ fi bajẹ? emi ko ha sàn fun ọ ju ọmọ mẹwa lọ bi?
Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa.
On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi.
On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.
O si ṣe bi o ti mbẹbẹ sibẹ niwaju Oluwa, bẹ̃ni Eli kiyesi ẹnu rẹ̀.
Njẹ Hanna, on nsọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kiki etè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀: nitorina ni Eli fi rò pe, o mu ọti-waini yó.
Eli si wi fun u pe, Iwọ o ti mu ọti-waini pẹ to? mu ọti-waini rẹ kuro lọdọ rẹ.
Hanna si dahun wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin oniròbinujẹ ọkàn: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn ọkàn mi li emi ntú jade niwaju Oluwa.
Má ṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ irò ati ibinujẹ inu mi ni mo ti nsọ disisiyi.
Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ.
On si wipe, Ki iranṣẹbinrin rẹ ki o ri ore-ọfẹ loju rẹ. Bẹ̃li obinrin na ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, ko si fà oju ro mọ.
Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn wolẹ sìn niwaju Oluwa, nwọn pada wá si ile wọn si Rama: Elkana si mọ aya rẹ̀; Oluwa si ranti rẹ̀.
Nitorina, o si ṣe, nigbati ọjọ rẹ̀ pe lẹhin igbati Hanna loyun, o si bi ọmọkunrin kan, o si pe orukọ rẹ̀ ni Samueli, pe, Nitoriti mo bere rẹ̀ lọwọ Oluwa.