I. Pet 4:13-14

I. Pet 4:13-14 YBCV

Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn. Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo.