I. Pet 4:1-19

I. Pet 4:1-19 YBCV

NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ; Ki ẹnyin ki o máṣe fi ìgba aiye nyin iyokù wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹ enia, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun. Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira. Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu, Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú. Nitori eyi li a sá ṣe wasu ihinrere fun awọn okú, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi enia nipa ti ara, ṣugbọn ki nwọn ki o le wà lãye si Ọlọrun nipa ti ẹmí. Ṣugbọn opin ohun gbogbo kù si dẹ̀dẹ: nitorina ki ẹnyin ki o wà li airekọja, ki ẹ si mã ṣọra ninu adura. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Ẹ mã ṣe ara nyin li alejò laisi ikùn sinu. Bi olukuluku ti ri ẹ̀bun gbà, bẹ̃ni ki ẹ mã ṣe ipinfunni rẹ̀ larin ara nyin, bi iriju rere ti onirũru ore-ọfẹ Ọlọrun. Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin. Olufẹ, ẹ máṣe ka idanwò iná ti mbẹ larin nyin eyiti o de si nyin lati dan nyin wò bi ẹnipe ohun àjeji li o de bá nyin: Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn. Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo. Ṣugbọn ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ninu nyin ki o jìya bi apania, tabi bi olè, tabi bi oluṣe-buburu, tabi bi ẹniti ntojubọ ọ̀ran ẹlomiran. Ṣugbọn bi o ba jìya bi Kristiani, ki oju ki o máṣe tì i; ṣugbọn ki o kuku yìn Ọlọrun logo ni orukọ yi. Nitoriti ìgba na de, ti idajọ yio bẹ̀rẹ lati ile Ọlọrun wá: bi o ba si tète ti ọdọ wa bẹ̀rẹ, opin awọn ti kò gbà ihinrere Ọlọrun gbọ́ yio ha ti ri? Biobaṣepe agbara káka li a fi gba olododo là, nibo ni alaiwà-bi-Ọlọrun on ẹlẹṣẹ yio gbé yọju si? Nitorina ẹ jẹ ki awọn ti njìya gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun, fi ọkàn wọn le e lọwọ pẹlu ni rere iṣe, bi ẹnipe fun Ẹlẹda olõtọ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Pet 4:1-19

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa