I. Pet 4:1-11

I. Pet 4:1-11 YBCV

NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ; Ki ẹnyin ki o máṣe fi ìgba aiye nyin iyokù wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹ enia, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun. Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira. Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu, Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú. Nitori eyi li a sá ṣe wasu ihinrere fun awọn okú, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi enia nipa ti ara, ṣugbọn ki nwọn ki o le wà lãye si Ọlọrun nipa ti ẹmí. Ṣugbọn opin ohun gbogbo kù si dẹ̀dẹ: nitorina ki ẹnyin ki o wà li airekọja, ki ẹ si mã ṣọra ninu adura. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Ẹ mã ṣe ara nyin li alejò laisi ikùn sinu. Bi olukuluku ti ri ẹ̀bun gbà, bẹ̃ni ki ẹ mã ṣe ipinfunni rẹ̀ larin ara nyin, bi iriju rere ti onirũru ore-ọfẹ Ọlọrun. Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Pet 4:1-11