Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ. Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí: Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ; Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi: Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.
Kà I. Pet 3
Feti si I. Pet 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 3:17-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò