BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn, Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin: Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀; Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun. Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn. Gẹgẹ bi Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, ti o npè e li oluwa: ọmọbinrin ẹniti ẹnyin iṣe, bi ẹnyin ba nṣe rere, ti ohunkohun kò si dẹruba nyìn.
Kà I. Pet 3
Feti si I. Pet 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 3:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò