I. Pet 2:1-12

I. Pet 2:1-12 YBCV

NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo. Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala, Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa: Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye, Ẹnyin pẹlu, bi okuta ãye, li a kọ ni ile ẹmí, alufa mimọ́, lati mã ru ẹbọ ẹmí, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi. Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i. Nitorina fun ẹnyin ti o gbagbọ́, ọla ni: ṣugbọn fun awọn ti kò gbagbọ́, okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o di pàtaki igunle, Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu. Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn: Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà. Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun; Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.