Bi ẹnyin ba si nkepè Baba, ẹniti nṣe idajọ gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku, li aiṣe ojuṣaju enia, ẹ mã lo igba atipo nyin ni ìbẹru: Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin, Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi; Ẹniti a ti mọ̀ tẹlẹ nitõtọ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ṣugbọn ti a fihan ni igba ikẹhin wọnyi nitori nyin
Kà I. Pet 1
Feti si I. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 1:17-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò