Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi:
Bi awọn eleti ọmọ, li aifi ara nyin dáṣà bi ifẹkufẹ atijọ ninu aimọ̀ nyin:
Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo:
Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹ jẹ mimọ́; nitoriti mo jẹ mimọ́.
Bi ẹnyin ba si nkepè Baba, ẹniti nṣe idajọ gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku, li aiṣe ojuṣaju enia, ẹ mã lo igba atipo nyin ni ìbẹru:
Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin,
Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi;
Ẹniti a ti mọ̀ tẹlẹ nitõtọ ṣaju ipilẹṣẹ aiye, ṣugbọn ti a fihan ni igba ikẹhin wọnyi nitori nyin,
Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.
Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá.
Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.
Nitoripe gbogbo ẹran ara dabi koriko, ati gbogbo ogo rẹ̀ bi itanná koriko. Koriko a mã gbẹ, itanná rẹ̀ a si rẹ̀ silẹ:
Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa duro titi lai. Ọ̀rọ yi na si ni ihinrere ti a wãsu fun nyin.