Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi: Bi awọn eleti ọmọ, li aifi ara nyin dáṣà bi ifẹkufẹ atijọ ninu aimọ̀ nyin: Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo: Nitori a ti kọ ọ pe, Ẹ jẹ mimọ́; nitoriti mo jẹ mimọ́. Bi ẹnyin ba si nkepè Baba, ẹniti nṣe idajọ gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku, li aiṣe ojuṣaju enia, ẹ mã lo igba atipo nyin ni ìbẹru: Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin, Bikoṣe ẹ̀jẹ iyebiye, bi ti ọdọ-agutan ti kò li abuku, ti kò si li abawọn, ani ẹ̀jẹ Kristi
Kà I. Pet 1
Feti si I. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 1:13-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò