PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia, ati Bitinia,
Gẹgẹ bi ìmọtẹlẹ Ọlọrun Baba, nipa isọdimimọ́ Ẹmí, si igbọran ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ Jesu Kristi: Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bi si i fun nyin.
Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú,
Sinu ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá, ti a ti fi pamọ́ li ọrun dè nyin,
Ẹnyin ti a npamọ́ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ́ si igbala, ti a mura lati fihàn ni igba ikẹhin.
Ninu eyiti ẹnyin nyọ̀ pipọ, bi o tilẹ ṣe pe nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọ̀pọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ:
Ki idanwò igbagbọ́ nyin, ti o ni iye lori jù wura ti iṣegbe lọ, bi o tilẹ ṣe pe iná li a fi ndán a wò, ki a le ri i fun iyìn, ati ọlá, ati ninu ogo ni igba ifarahàn Jesu Kristi:
Ẹniti ẹnyin fẹ lairi, ẹniti ẹnyin gbagbọ, bi o tilẹ ṣepe ẹ kò ri i nisisiyi, ẹnyin si nyọ ayọ̀ ti a kò le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo:
Ẹnyin si ngbà opin igbagbọ́ nyin, ani igbala ọkàn nyin