Solomoni si fẹ Oluwa, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rẹ̀: ṣugbọn kiki pe, o nrubọ, o si nfi turari jona ni ibi-giga.
Ọba si lọ si Gibeoni lati rubọ nibẹ; nitori ibẹ ni ibi-giga nlanla: ẹgbẹrun ọrẹ ẹbọ-sisun ni Solomoni ru lori pẹpẹ na.
Ni Gibeoni ni Oluwa fi ara rẹ̀ hàn Solomoni loju alá li oru: Ọlọrun si wipe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.
Solomoni si wipe, Iwọ ti ṣe ore nla fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi, gẹgẹ bi o ti rin niwaju rẹ li otitọ ati li ododo, ati ni iduro-ṣinṣin ọkàn pẹlu rẹ, iwọ si pa ore nla yi mọ fun u lati fun u li ọmọkunrin ti o joko lori itẹ rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ri loni yi.
Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun mi, iwọ ti fi iranṣẹ rẹ jẹ ọba ni ipo Dafidi, baba mi: ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ̀ jijade ati wiwọle.
Iranṣẹ rẹ si mbẹ lãrin awọn enia rẹ ti iwọ ti yàn, enia pupọ, ti a kò le moye, ti a kò si lè kà fun ọ̀pọlọpọ.
Nitorina, fi ọkàn imoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ̀ iyatọ rere ati buburu; nitori tali o le ṣe idajọ awọn enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi?
Ọ̀rọ na si dara loju Oluwa, nitoriti Solomoni bère nkan yi.
Ọlọrun si wi fun u pe, Nitoriti iwọ bère nkan yi, ti iwọ kò si bère ẹmi gigun fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ọlá fun ara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò bère ẹmi awọn ọta rẹ; ṣugbọn iwọ bère oye fun ara rẹ lati mọ̀ ẹjọ-idá;
Wò o, emi ti ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, wò o, emi fun ọ ni ọkàn ọgbọ́n ati imoye; tobẹ̃ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣãju rẹ, bẹ̃ni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ.
Ati eyiti iwọ kò bere, emi o fun ọ pẹlu ati ọrọ̀ ati ọlá: tobẹ̃ ti kì yio si ọkan ninu awọn ọba ti yio dabi rẹ.
Bi iwọ o ba si rìn ni ọ̀na mi lati pa aṣẹ ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ ti rìn, emi o si sún ọjọ rẹ siwaju.
Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.
Nigbana ni obinrin meji, ti iṣe àgbere, wá sọdọ ọba nwọn si duro niwaju rẹ̀.
Ọkan ninu wọn si wipe, Jọwọ, oluwa mi, emi ati obinrin yi ngbe ile kan; emi si bi ọmọ ni ile pẹlu rẹ̀.
O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile.
Ọmọ obinrin yi si kú li oru; nitoriti o sun le e.
O si dide li ọ̀ganjọ, o si gbe ọmọ mi lati iha mi, nigbati iranṣẹ-birin rẹ sun, o si tẹ́ ẹ si aiya rẹ̀, o si tẹ́ okú ọmọ tirẹ̀ si aiya mi.
Mo si dide li owurọ lati fi ọmú fun ọmọ mi, si wò o, o ti kú: ṣugbọn nigbati mo wò o fin li owurọ̀, si wò o, kì iṣe ọmọ mi ti mo bí.
Obinrin keji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi alãye ni ọmọ mi, eyi okú li ọmọ rẹ, eyi si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye si li ọmọ mi. Bayi ni nwọn nsọ niwaju ọba.
Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.
Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba.
Ọba si wipe, Ẹ là eyi alãye ọmọ si meji, ki ẹ si mu idaji fun ọkan ati idaji fun ekeji.
Obinrin ti eyi alãye ọmọ iṣe tirẹ̀ si wi fun ọba, nitori ti inu rẹ̀ yọ́ si ọmọ rẹ̀, o si wipe, Jọwọ, oluwa mi, ẹ fun u ni eyi alãye ọmọ, ki a máṣe pa a rara. Ṣugbọn eyi ekeji si wipe, kì yio jẹ temi tabi tirẹ, ẹ là a.
Ọba si dahùn o si wipe, ẹ fi alãye ọmọ fun u, ki ẹ má si ṣe pa a: on ni iya rẹ̀.
Gbogbo Israeli si gbọ́ idajọ ti ọba ṣe; nwọn si bẹ̀ru niwaju ọba: nitoriti nwọn ri i pe, ọgbọ́n Ọlọrun wà ninu rẹ̀, lati ṣe idajọ.