I. A. Ọba 2

2
Ìkìlọ̀ Ìkẹyìn Tí Dafidi ṣe fún Solomoni
1ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe:
2Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin.
3Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si.
4Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli.
5Iwọ si mọ̀ pẹlu, ohun ti Joabu, ọmọ Seruiah, ṣe si mi, ati ohun ti o ṣe si balogun meji ninu awọn ọgagun Israeli, si Abneri, ọmọ Neri, ati si Amasa, ọmọ Jeteri, o si pa wọn, o si ta ẹ̀jẹ ogun silẹ li alafia, o si fi ẹ̀jẹ ogun si ara àmure rẹ̀ ti mbẹ li ẹ̀gbẹ rẹ̀, ati si ara salubata rẹ̀ ti mbẹ li ẹsẹ rẹ̀.
6Nitorina, ki o ṣe gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ, ki o má si jẹ ki ewu ori rẹ̀ ki o sọkalẹ lọ si isa-okú li alafia.
7Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ.
8Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ.
9Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.
Ikú Dafidi
10Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi.
11Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
12Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi.
Ikú Adonija
13Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni.
14On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi:
15On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá.
16Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi.
17O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya.
18Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ.
19Batṣeba si tọ Solomoni ọba lọ, lati sọ fun u nitori Adonijah. Ọba si dide lati pade rẹ̀, o si tẹ ara rẹ̀ ba fun u, o si joko lori itẹ́ rẹ̀ o si tẹ́ itẹ fun iya ọba, on si joko lọwọ ọtun rẹ̀.
20On si wipe, Ibere kekere kan li emi ni ibere lọwọ rẹ; máṣe dù mi. On si wipe, mã tọrọ, iya mi; nitoriti emi kì yio dù ọ.
21On si wipe, jẹ ki a fi Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, arakunrin rẹ, li aya.
22Solomoni ọba si dahùn, o si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi mbere Abiṣagi, ara Ṣunemu, fun Adonijah, kuku bere ijọba fun u pẹlu; nitori ẹgbọ́n mi ni iṣe; fun on pãpa, ati fun Abiatari, alufa, ati fun Joabu, ọmọ Seruiah.
23Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀.
24Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah.
25Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú.
Wọ́n lé Abiatari kúrò ní ìlú, wọ́n sì pa Joabu
26Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ.
27Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo.
28Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu.
29A si sọ fun Solomoni ọba pe, Joabu ti sá sinu agọ Oluwa; si wò o, o sunmọ pẹpẹ, Solomoni si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, pe, Lọ, ki o si kọlù u.
30Benaiah si wá sinu agọ Oluwa, o si wi fun u pe, Bayi li ọba wi, pe, Jade wá. On si wipe, Bẹ̃kọ̀; ṣugbọn nihinyi li emi o kú. Benaiah si mu èsi fun ọba wá pe, Bayi ni Joabu wi, bayi ni o si dá mi lohùn.
31Ọba si wi fun u pe, Ṣe gẹgẹ bi o ti wi ki o si kọlù u, ki o si sin i, ki iwọ ki o le mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lọdọ mi ati kuro lọdọ ile baba mi, ti Joabu ti ta silẹ.
32Oluwa yio si yi ẹ̀jẹ rẹ̀ pada sori rẹ̀, nitoriti o kọlù ọkunrin meji ti o ṣe olododo, ti o sàn jù on tikararẹ̀ lọ, o si fi idà pa wọn. Dafidi baba mi kò si mọ̀, ani, Abneri, ọmọ Neri, olori ogun, ati Amasa, ọmọ Jeteri, olori ogun Juda.
33Ẹ̀jẹ wọn yio si pada sori Joabu, ati sori iru-ọmọ rẹ̀ lailai: ṣugbọn si Dafidi ati si iru-ọmọ rẹ̀, ati si ile rẹ̀, ati si itẹ́ rẹ̀, alafia yio wà lati ọdọ Oluwa wá,
34Benaiah, ọmọ Jehoiada, si goke, o si kọlù u, ó si pa a: a si sin i ni ile rẹ̀ li aginju.
35Ọba si fi Benaiah, ọmọ Jehoiada, jẹ olori-ogun ni ipò rẹ̀, ati Sadoku alufa ni ọba fi si ipò Abiatari.
Ikú Ṣimei
36Ọba si ranṣẹ, o si pe Ṣimei, o si wi fun u pe, Kọ́ ile fun ara rẹ ni Jerusalemu, ki o si ma gbe ibẹ̀, ki o má si ṣe jade lati ibẹ lọ si ibikibi.
37Yio si ṣe li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si kọja odò Kidroni, ki iwọ mọ̀ dajudaju pe, Kikú ni iwọ o kú; ẹ̀jẹ rẹ yio wà lori ara rẹ.
38Ṣimei si wi fun ọba pe, Ọrọ na dara, gẹgẹ bi oluwa mi ọba ti wi, bẹ̃ gẹgẹ ni iranṣẹ rẹ yio ṣe. Ṣimei si gbe Jerusalemu li ọjọ pupọ.
39O si ṣe lẹhin ọdun mẹta, awọn ọmọ-ọdọ Ṣimei meji si lọ sọdọ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati. Nwọn si rò fun Ṣimei pe, Wo o, awọn ọmọ-ọdọ rẹ mbẹ ni Gati.
40Ṣimei si dide, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gari, o si lọ, o si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ bọ̀ lati Gati.
41A si rò fun Solomoni pe, Ṣimei ti lọ lati Jerusalemu si Gati, o si pada bọ̀.
42Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara.
43Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ?
44Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ.
45A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai.
46Ọba si paṣẹ fun Benaiah ọmọ Jehoiada, o si jade lọ, o si kọlù u, o si kú. A si fi idi ijọba mulẹ li ọwọ́ Solomoni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. A. Ọba 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀