Elijah si wi fun Ahabu pe, Goke lọ, jẹ, ki o si mu; nitori iró ọ̀pọlọpọ òjo mbẹ. Bẹ̃ni Ahabu goke lọ lati jẹ ati lati mu. Elijah si gun ori oke Karmeli lọ; o si tẹriba o si fi oju rẹ̀ si agbedemeji ẽkun rẹ̀, O si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Goke lọ nisisiyi, ki o si wò iha okun. On si goke lọ, o si wò, o si wipe, Kò si nkan. O si wipe, Tun lọ nigba meje. O si ṣe, ni igba keje, o si wipe, Kiyesi i, awọsanmọ kekere kan dide lati inu okun, gẹgẹ bi ọwọ́ enia. On si wipe, Goke lọ, wi fun Ahabu pe, Di kẹkẹ́ rẹ, ki o si sọkalẹ, ki òjo ki o má ba da ọ duro. O si ṣe, nigba diẹ si i, ọrun si ṣu fun awọsanmọ on iji, òjo pupọ si rọ̀. Ahabu si gun kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli. Ọwọ́ Oluwa si mbẹ lara Elijah: o si di amure ẹ̀gbẹ rẹ̀, o si sare niwaju Ahabu titi de Jesreeli.
Kà I. A. Ọba 18
Feti si I. A. Ọba 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 18:41-46
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò