Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀.
Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin.
Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba.
Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa.
O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria.
Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀.
Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.
Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun,
Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ.
O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,
O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria.
Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu.