Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere. Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ. Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun. Nitori bi mo ti jẹ omnira kuro lọdọ gbogbo enia, mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo wọn, ki emi ki o le jère pipọ si i. Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin; Fun awọn alailofin bi alailofin (emi kì iṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi mbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jère awọn alailofin. Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri. Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin.
Kà I. Kor 9
Feti si I. Kor 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 9:16-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò