I. Kor 7:6-9

I. Kor 7:6-9 YBCV

Ṣugbọn mo sọ eyi bi imọran, kì iṣe bi aṣẹ. Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini. Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà. Ṣugbọn bi nwọn kò bá le maraduro, ki nwọn ki o gbeyawo: nitori o san lati gbeyawo jù ati ṣe ifẹkufẹ lọ.