I. Kor 6:15-18

I. Kor 6:15-18 YBCV

Ẹnyin kò mọ̀ pe ẹ̀ya-ara Kristi li ara nyin iṣe? njẹ emi o ha mu ẹ̀ya-ara Kristi, ki emi ki o si fi ṣe ẹ̀ya-ara àgbere bi? ki a má ri. Tabi, ẹnyin kò mọ̀ pe ẹniti o ba dàpọ mọ́ àgbere di ara kan? nitoriti o wipe, Awọn mejeji ni yio di ara kan. Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan. Ẹ mã sá fun àgbere. Gbogbo ẹ̀ṣẹ ti enia ndá o wà lode ara; ṣugbọn ẹniti o nṣe àgbere nṣẹ̀ si ara on tikararẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Kor 6:15-18