I. Kor 15:35-49

I. Kor 15:35-49 YBCV

Ṣugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si? Iwọ alaimoye, ohun ti iwọ fọnrugbin ki iyè bikoṣepe o ba kú: Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran. Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀. Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ. Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ. Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo. Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ: A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara: A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ. Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye. Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí. Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni. Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun. Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun.