Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si? Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu. Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde? Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide: Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ. Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé. Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia. Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀. Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro. Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun. Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ. Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo. Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú? Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ.
Kà I. Kor 15
Feti si I. Kor 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 15:12-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò