BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro.
Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le ṣí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan.
Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi.
Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀,
Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu;
Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ;
A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.
Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.
Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan.
Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin.
Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ.
Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.
Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.