Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá. Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu. Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a. Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa.
Kà I. Kor 10
Feti si I. Kor 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 10:6-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò