Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa. Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna. Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin. Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi. A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si?
Kà I. Kor 1
Feti si I. Kor 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 1:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò