I. Kro 6

6
Ìran Àwọn Olórí Àlùfáàa
1AWỌN ọmọ Lefi; Gerṣoni, Kohati, ati Merari.
2Ati awọn Kohati; Amramu, Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli.
3Ati awọn Amramu; Aaroni, ati Mose, ati Miriamu. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.
4Eleasari bi Finehasi, Finehasi si bi Abiṣua,
5Abiṣua si bi Bukki, Bukki si bi Ussi,
6Ussi si bi Serahiah, Serahiah si bi Meraioti,
7Meraioti bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu.
8Ahitubu si bi Sadoku, Sadoku si bi Ahimaasi,
9Ahimaasi si bi Asariah, Asariah si bi Johanani,
10Johanani si bi Asariah (on na li ẹniti nṣiṣẹ alufa ni tempili ti Solomoni kọ́ ni Jerusalemu;)
11Asariah si bi Amariah, Amariah si bi Ahitubu,
12Ahitubu si bi Sadoki, Sadoki si bi Ṣallumu,
13Ṣallumu si bi Hilkiah, Hilkiah si bi Asariah,
14Asariah si bi Seraiah, Seraiah si bi Jehosadaki,
15Jehosadaki si lọ si oko ẹrú, nigbati Oluwa kó Juda ati Jerusalemu lọ nipa ọwọ Nebukadnessari.
Àwọn Ìran Lefi Yòókù
16Awọn ọmọ Lefi; Gersọmu, Kohati, ati Merari.
17Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Gerṣomu, Libni, ati Ṣimei.
18Awọn ọmọ Kohati ni, Amramu, ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli.
19Awọn ọmọ Merari; Mahli ati Muṣi. Wọnyi si ni idile awọn ọmọ Lefi, gẹgẹ bi awọn baba wọn.
20Ti Gerṣomu; Libni ọmọ rẹ̀, Jahati ọmọ rẹ̀, Simma ọmọ rẹ̀.
21Joa ọmọ rẹ̀, Iddo ọmọ rẹ̀, Sera ọmọ rẹ̀, Jeaterai ọmọ rẹ̀.
22Awọn ọmọ Kohati; Amminadabu ọmọ rẹ̀, Kora ọmọ rẹ̀, Assiri ọmọ rẹ̀.
23Elkana ọmọ rẹ̀, ati Ebiasafu ọmọ rẹ̀, ati Assiri ọmọ rẹ̀,
24Tahati ọmọ rẹ̀, Urieli ọmọ rẹ̀, Ussiah ọmọ rẹ̀, ati Ṣaulu ọmọ rẹ̀,
25Ati awọn ọmọ Elkana; Amasai, ati Ahimoti.
26Niti Elkana: awọn ọmọ Elkana; Sofai ọmọ rẹ̀, ati Nahati ọmọ rẹ̀,
27Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀.
28Awọn ọmọ Samueli; akọbi Faṣni, ati Abiah.
29Awọn ọmọ Merari; Mahli, Libni, ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀,
30Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀, Asaiah ọmọ rẹ̀,
Àwọn Ẹgbẹ́ Akọrin Tẹmpili
31Wọnyi si ni awọn ti Dafidi yàn ṣe olori iṣẹ orin ni ile Oluwa, lẹhin igbati apoti-ẹ̀ri Oluwa ti ni isimi.
32Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn.
33Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,
34Ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
35Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
37Ọmọ Tahati, ọmọ Assiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,
38Ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli.
39Ati arakunrin rẹ̀ Asafu, ti o duro li ọwọ ọ̀tun rẹ̀, ani Asafu, ọmọ Berakiah, ọmọ Ṣimea,
40Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah.
41Ọmọ Etni, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
42Ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,
43Ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Lefi.
44Awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Merari duro lọwọ osi: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluku,
45Ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
46Ọmọ Amsi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣameri.
47Ọmọ Mahli, ọmọ Muṣi ọmọ Merari, ọmọ Lefi,
48Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.
Ìran Aaroni
49Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.
50Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
51Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,
52Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,
53Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.
Ibi tí àwọn Ọmọ Lefi ń gbé
54Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini.
55Nwọn si fun wọn ni Hebroni ni ilẹ Juda, ati ìgberiko rẹ̀ yi i kakiri.
56Ṣugbọn oko ilu na, ati ileto wọn, ni nwọn fun Kalebu ọmọ Jefunne.
57Nwọn si fi ilu Juda fun awọn ọmọ Aaroni, ani Hebroni, ilu àbo ati Libna pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jattiri, ati Eṣtemoa, pẹlu ìgberiko wọn,
58Ati Hileni pẹlu ìgberiko rẹ̀, Debiri pẹlu ìgberiko rẹ̀,
59Ati Aṣani pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-ṣemeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀:
60Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini; Geba pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Alemeti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anatoti pẹlu ìgberiko rẹ̀. Gbogbo ilu wọn ni idile wọn jẹ ilu mẹtala.
61Ati fun awọn ọmọ Kohati, ti o kù ni idile ẹ̀ya na, li a fi keke fi ilu mẹwa fun, ninu àbọ ẹ̀ya, ani lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse.
62Ati fun awọn ọmọ Gerṣomu ni idile wọn, lati inu ẹ̀ya Issakari, ati inu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati lati inu ẹ̀ya Manasse ni Baṣani, ilu mẹtala.
63Fun awọn ọmọ Merari ni idile wọn li a fi keké fi ilu mejila fun, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati lati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni,
64Awọn ọmọ Israeli fi ilu wọnyi fun awọn ọmọ Lefi pẹlu ìgberiko wọn.
65Nwọn si fi keké fi ilu wọnyi ti a da orukọ wọn fun ni lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini.
66Ati iyokù ninu idile awọn ọmọ Kohati ni ilu li àgbegbe wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu.
67Nwọn si fi ninu ilu àbo fun wọn, Ṣekemu li òke Efraimu pẹlu ìgberiko rẹ̀; Geseri pẹlu ìgberiko rẹ̀,
68Ati Jokneamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bet-horoni pẹlu ìgberiko rẹ̀,
69Ati Aijaloni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Gatrimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀:
70Ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse; Aneri pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Bileamu pẹlu ìgberiko rẹ̀, fun idile awọn ọmọ Kohati iyokù.
71Awọn ọmọ Gerṣomu lati inu idile àbọ ẹ̀ya Manasse li a fi Golani ni Baṣani fun pẹlu ìgberiko rẹ̀; ati Aṣtaroti pẹlu ìgberiko rẹ̀,
72Ati lati inu ẹ̀ya Issakari; Kadeṣi pẹlu ìgberiko rẹ̀; Daberati pẹlu ìgberiko rẹ̀,
73Ati Ramoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Anemu pẹlu ìgberiko rẹ̀:
74Ati lati inu ẹ̀ya Aṣeri; Maṣali pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Abdoni pẹlu ìgberiko rẹ̀.
75Ati Hakoku pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Rehobu pẹlu ìgberiko rẹ̀:
76Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.
77Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni:
78Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,
79Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀:
80Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.
81Ati Heṣboni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jaseri pẹlu ìgberiko rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀