I. Kro 5

5
Ìran Reubẹni
1NJẸ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (nitori on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣepe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ, a fi ogun ibi rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a kì yio si ka itan-idile na gẹgẹ bi ipò ibi.
2Nitori Juda bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wá; ṣugbọn ogún ibi jẹ ti Josefu:)
3Mo ni, awọn ọmọ Rubeni akọbi Israeli ni Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi.
4Awọn ọmọ Joeli; Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀,
5Mika ọmọ rẹ̀, Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀,
6Beera ọmọ rẹ̀, ti Tiglat-pilneseri ọba Assiria kò ni ìgbekun lọ; ijoye awọn ọmọ Rubeni ni iṣe.
7Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa idile wọn, nigbati a nkà itàn-idile iran wọn, Jeieli, ati Sekariah ni olori.
8Ati Bela ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli, ti ngbe Aroeri, ani titi de Nebo ati Baalmeoni:
9Ati niha ariwa, o tẹ̀do lọ titi de ati-wọ̀ aginju lati odò Eufrate; nitoriti ẹran ọ̀sin wọn pọ̀ si i ni ilẹ Gileadi.
10Ati li ọjọ Saulu, nwọn ba awọn ọmọ Hagari jagun, ẹniti o ṣubu nipa ọwọ wọn: nwọn si ngbe inu agọ wọn ni gbogbo ilẹ ariwa Gileadi.
Àwọn Ìran Gadi
11Ati awọn ọmọ Gadi ngbe ọkánkan wọn, ni ilẹ Baṣani titi de Salka:
12Joeli olori, ati Ṣafamu àtẹle, ati Jaanai, ati Ṣafati ni Baṣani.
13Ati awọn arakunrin wọn ti ile awọn baba wọn ni Mikaeli, ati Meṣullamu, ati Ṣeba, ati Jorai, ati Jakani, ati Sia, ati Heberi, meje.
14Wọnyi li awọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi;
15Adi, ọmọ Abdieli, ọmọ Guni, olori ile awọn baba wọn.
16Nwọn si ngbe Gileadi ni Baṣani, ati ninu awọn ilu rẹ̀, ati ninu gbogbo igberiko Ṣaroni, li àgbegbe wọn.
17Gbogbo wọnyi li a kà nipa itan-idile, li ọjọ Jotamu ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọba Israeli,
Àwọn ọmọ ogun àwọn ẹ̀yà ìhà ìlà oòrùn
18Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na.
19Nwọn si ba awọn ọmọ Hagari jagun, pẹlu Jeturi, ati Nefiṣi ati Nadabu.
20A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e.
21Nwọn si kó ẹran ọ̀sin wọn lọ; ibakasiẹ ẹgbãmẹ̃dọgbọ̀n ati àgutan ọkẹ mejila o le ẹgbãrun, ati kẹtẹkẹtẹ ẹgbã, ati enia ọkẹ marun.
22Nitori ọ̀pọlọpọ li o ṣubu ti a pa, nitori lati ọdọ Ọlọrun li ogun na. Nwọn si joko ni ipò wọn titi di igbà ikolọ si ìgbekun.
Ìdajì Ẹ̀yà Manase tí ń gbé Ìhà Ìlà Oòrùn
23Awọn ọmọkunrin àbọ ẹ̀ya Manasse joko ni ilẹ na: nwọn bi si i lati Baṣani titi de Baal-hermoni, ati Seniri, ati titi de òke Hermoni.
24Wọnyi si li awọn olori ile awọn baba wọn, Eferi, ati Iṣi, ati Elieli, ati Asrieli, ati Jeremiah, ati Hodafiah, ati Jahdieli, awọn alagbara akọni ọkunrin, ọkunrin olokiki, ati olori ile awọn baba wọn.
A Kó Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Ìlà Oòrùn Lẹ́rú Lọ
25Nwọn si ṣẹ̀ si Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si ṣe àgbere tọ awọn ọlọrun enia ilẹ na lẹhin, ti Ọlọrun ti parun ni iwaju wọn.
26Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa