I. Kro 24

24
Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáà
1NJẸ bi a ti pín awọn ọmọ Aaroni ni wọnyi. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.
2Ṣugbọn Nadabu ati Abihu kú ṣaju baba wọn, nwọn kò si li ọmọ: nitorina ni Eleasari ati Itamari fi ṣiṣẹ alufa.
3Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn.
4A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn.
5Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.
6Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari.
7Njẹ iṣẹkeké ekini jade fun Jehoiaribu, ekeji fun Jedaiah,
8Ẹkẹta fun Harimu, ẹkẹrin fun Seorimu,
9Ẹkarun fun Malkijah, ẹkẹfa fun Mijamini,
10Ekeje fun Hakkosi, ẹkẹjọ fun Abijah,
11Ẹkẹsan fun Jeṣua, ẹkẹwa fun Ṣekaniah,
12Ẹkọkanla fun Eliaṣibu, ekejila fun Jakimu,
13Ẹkẹtala fun Huppa, ẹkẹrinla fun Jeṣebeabu,
14Ẹkẹdogun fun Bilga, ẹkẹrindilogun fun Immeri,
15Ẹkẹtadilogun fun Heṣiri, ekejidilogun fun Afisesi,
16Ẹkọkandilogun fun Petahiah, ogun fun Jehesekeli,
17Ẹkọkanlelogun fun Jakini, ekejilelogun fun Gamuli,
18Ẹkẹtalelogun fun Delaiah, ẹkẹrinlelogun fun Maasiah.
19Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.
Orúkọ Àwọn Ọmọ Lefi
20Iyokù awọn ọmọ Lefi ni wọnyi: Ninu awọn ọmọ Amramu; Ṣubaeli: ninu awọn ọmọ Ṣubaeli; Jehediah.
21Nipa ti Rehabiah; ninu awọn ọmọ Rehabiah, ekini Iṣṣiah.
22Ninu awọn Ishari; Ṣelomoti; ninu awọn ọmọ Ṣelomoti; Jahati.
23Awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ikini; Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, Jekamamu ẹkẹrin.
24Awọn ọmọ Ussieli; Mika: awọn ọmọ Mika; Ṣamiri.
25Arakunrin Mika ni Iṣṣiah; ninu awọn ọmọ Iṣṣiah; Sekariah.
26Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno;
27Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri.
28Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin.
29Nipa ti Kiṣi: ọmọ Kiṣi ni Jerameeli.
30Awọn ọmọ Muṣi pẹlu; Mali, ati Ederi, ati Jerimoti. Wọnyi li ọmọ awọn ọmọ Lefi nipa ile baba wọn.
31Awọn wọnyi pẹlu ṣẹ keké gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Aaroni niwaju Dafidi ọba ati Sadoku, ati Ahimeleki, ati awọn olori awọn baba awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: olori awọn baba gẹgẹ bi aburo rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀