SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli. Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn. Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi. Ṣugbọn ọ̀rọ ọba bori ti Joabu, nitorina Joabu jade lọ, o si la gbogbo Israeli ja, o si de Jerusalemu. Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà. Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu. Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi.
Kà I. Kro 21
Feti si I. Kro 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 21:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò