I. Kro 21:1-17

I. Kro 21:1-17 YBCV

SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli. Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn. Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi. Ṣugbọn ọ̀rọ ọba bori ti Joabu, nitorina Joabu jade lọ, o si la gbogbo Israeli ja, o si de Jerusalemu. Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà. Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu. Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi. Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe, Lọ ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, mo fi nkan mẹta lọ̀ ọ: yàn ọkan ninu wọn ki emi ki o le ṣe e si ọ. Bẹ̃ni Gadi tọ Dafidi wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, yan fun ara rẹ, Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi. Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia. Bẹ̃ li Oluwa ran ajakalẹ arun si Israeli: awọn ti o ṣubu ni Israeli jẹ ẹgbã marundilogoji enia. Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi. Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi kọ́ ha paṣẹ lati kaye awọn enia? ani emi li ẹniti o ṣẹ̀ ti mo si ṣe buburu pãpã; ṣugbọn bi o ṣe ti agutan wọnyi, kini nwọn ṣe? Emi bẹ̀ ọ, Oluwa Ọlọrun mi, jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà li ara mi, ati lara ile baba mi; ṣugbọn ki o máṣe li ara awọn enia rẹ ti a o fi arùn kọlu wọn.