I. Kro 16:1-36

I. Kro 16:1-36 YBCV

BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun, Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa. O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan. O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli: Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan; Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun. Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, ẹ pè orukọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ́ orin mimọ́ si i, ẹ ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki ọkàn awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ̀, ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀; Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀. On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran; Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye: Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀. Nwọn si nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ati lati ijọba kan de ọdọ enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ìwọsi, nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn, Wipe, Ẹ má ṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi, ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi. Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia. Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ. Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun. Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀. Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye, aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi. Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba. Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀. Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ. Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.