I. Kro 1

1
Ìran Adamu títí Dé Orí Abrahamu
(Gẹn 5:1-32; 10:1-32; 11:10-26)
1ADAMU, Seti, Enoṣi,
2Kenani, Mahalaleeli, Jeredi,
3Henoki, Metusela, Lameki,
4Noa, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti,
5Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi,
6Ati awọn ọmọ Gomeri; Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togarma.
7Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu.
8Awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, Puti, ati Kenaani.
9Ati awọn ọmọ Kuṣi; Ṣeba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka. Ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba ati Dedani.
10Kuṣi si bi Nimrodu: on bẹ̀rẹ si di alagbara li aiye.
11Misraimu si bi Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,
12Ati Patrusimu, ati Kasluhimu, (lọdọ ẹniti awọn ara Filistia ti wá,) ati Kaftorimu.
13Kenaani si bi Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,
14Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,
15Ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,
16Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati.
17Awọn ọmọ Ṣemu; Elamu, ati Assuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu, ati Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Meṣeki.
18Arfaksadi si bi Ṣela; Ṣela si bi Eberi.
19Ati fun Eberi li a bi ọmọkunrin meji: orukọ ọkan ni Pelegi; nitori li ọjọ rẹ̀ li a pin aiye niya: orukọ arakunrin rẹ̀ si ni Joktani.
20Joktani si bi Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,
21Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,
22Ati Ebali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,
23Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Joktani.
24Ṣemu, Arfaksadi, Ṣela,
25Eberi, Pelegi, Reu,
26Serugu, Nahori, Tera,
27Abramu; on na ni Abrahamu,
Ìran Iṣimaeli
(Gẹn 25:12-16)
28Awọn ọmọ Abrahamu; Isaaki, ati Iṣmaeli.
29Wọnyi ni iran wọn: akọbi Iṣmaeli, Nebaioti; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu,
30Miṣma, ati Duma, Massa, Hadadi, ati Tema,
31Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli.
32Ati awọn ọmọ Ketura, obinrin Abrahamu: on bi Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaki, ati Ṣua. Ati awọn ọmọ Jokṣani: Ṣeba, ati Dedani.
33Ati awọn ọmọ Midiani: Efa, ati Eferi, ati Henoki, ati Abida, ani Eldaa. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Ketura.
Àwọn Ìran Esau
(Gẹn 36:1-19)
34Abrahamu si bi Isaaki. Awọn ọmọ Isaaki; Esau ati Israeli.
35Awọn ọmọ Esau; Elifasi, Reueli, ati Jeusi, ati Jaalamu, ati Kora.
36Awọn ọmọ Elifasi; Temani, ati Omari, Sefi, ati Gatamu, Kenasi, ati Timna, ati Amaleki.
37Awọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma, ati Missa.
Àwọn tí ń gbé Edomu tẹ́lẹ̀
(Gẹn 36:20-30)
38Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Diṣoni, ati Esari, ati Diṣani.
39Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si ni arabinrin Lotani.
40Awọn ọmọ Ṣobali; Aliani, ati Manahati, ati Ebali, Ṣefi, ati Onamu. Ati awọn ọmọ Sibeoni; Aiah, ati Ana.
41Awọn ọmọ Ana; Diṣoni. Ati awọn ọmọ Diṣoni; Amrani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.
42Awọn ọmọ Eseri; Bilhani, ati Safani, ati Jakani. Awọn ọmọ Diṣani; Usi, ati Arani.
Àwọn Ọba Edomu
(Gẹn 36:31-43)
43Wọnyi si ni awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan to jẹ lori awọn ọmọ Israeli: Bela ọmọ Beori: orukọ ilu rẹ̀ si ni Dinhaba.
44Nigbati Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.
45Nigbati Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ awọn ara Temani si jọba ni ipò rẹ̀.
46Nigbati Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ti o kọlu Midiani ni ìgbẹ Moabu, jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Afiti.
47Nigbati Hadadi kú, Samla ti Masreka jọba ni ipò rẹ̀.
48Nigbati Samla kú, Ṣaulu ti Rehoboti leti odò jọba ni ipò rẹ̀.
49Nigbati Ṣaulu kú, Baal-hanani, ọmọ Akbori, jọba ni ipò rẹ̀.
50Nigbati Baal-hanani kú, Hadadi si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Pai; orukọ aya rẹ̀ si ni Mehetabeeli, ọmọbinrin Matredi, ọmọbinrin Mesahabu.
51Hadadi si kú. Awọn bãlẹ Edomu ni; Timna bãlẹ, Aliah bãlẹ, Jeteti bãlẹ.
52Aholibama bãlẹ, Ela bãlẹ, Pinoni bãlẹ,
53Kenasi bãlẹ, Temani bãlẹ, Mibsari bãlẹ,
54Magdieli bãlẹ, Iramu bãlẹ. Wọnyi ni awọn bãlẹ Edomu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa