SAKARAYA 5
5
Ìran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò
1Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. 2Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).”
3Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.” 4OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.”
Ìran nípa Obinrin Tó Wà ninu Apẹ̀rẹ̀
5Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.”
6Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.”
7Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà.
8Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada. 9Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.
10Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?”
11Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAKARAYA 5: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010