Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ ninu àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gbadura fún. Ṣugbọn Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́dọ̀ Ọlọrun lọ́nà tí a kò lè fi ẹnu sọ. Ọlọrun, Olùmọ̀ràn ọkàn, mọ èrò tí ó wà lọ́kàn Ẹ̀mí, nítorí Ẹ̀mí níí máa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun bí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti fẹ́. Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé. Nítorí àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó yà sọ́tọ̀ kí wọ́n lè dàbí Ọmọ rẹ̀, kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè jẹ́ àkọ́bí láàrin ọpọlọpọ mọ̀lẹ́bí. Àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó pè. Àwọn tí ó pè ni ó dá láre. Àwọn tí ó sì dá láre ni ó dá lọ́lá.
Kà ROMU 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 8:26-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò