ROMU 5:5-11

ROMU 5:5-11 YCE

Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa. Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún ROMU 5:5-11

ROMU 5:5-11 - Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.
Nítorí nígbà tí a jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó wọ̀, Kristi kú fún àwa tí kò ka Ọlọrun sí. Bóyá ni a lè rí ẹni tí yóo fẹ́ kú fún olódodo. Ṣugbọn ó ṣeéṣe kí á rí ẹni tí yóo ní ìgboyà láti kú fún eniyan rere. Ṣugbọn Ọlọrun fihàn wá pé òun fẹ́ràn wa ní ti pé nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Bí ó bá lè kú fún wa nígbà tí a sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, nisinsinyii tí Ọlọrun ti dá wa láre nítorí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, a óo sì torí rẹ̀ gbà wá kúrò ninu ibinu tí ń bọ̀. Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.