Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre. Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́.
Kà ROMU 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 3:25-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò