ROMU 2:14-15

ROMU 2:14-15 YCE

Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi