ROMU 2:1-16

ROMU 2:1-16 YCE

Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún. Ṣugbọn a mọ̀ pé Ọlọrun ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi. Ìwọ tí ò ń dá àwọn ẹlòmíràn tí ó ń ṣe nǹkan wọnyi lẹ́jọ́, tí ìwọ alára sì ń ṣe nǹkankan náà, ṣé o wá rò pé ìwọ óo bọ́ ninu ìdájọ́ Ọlọrun ni? Àbí o fi ojú tẹmbẹlu ọpọlọpọ oore Ọlọrun ni, ati ìfaradà rẹ̀ ati sùúrù rẹ̀? O kò mọ̀ pé kí o lè ronupiwada ni gbogbo oore tí Ọlọrun ń ṣe, Ṣugbọn nípa oríkunkun ati agídí ọkàn rẹ, ò ń fi ibinu Ọlọrun pamọ́ fún ara rẹ títí di ọjọ́ ibinu ati ìgbà tí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun yóo dé. Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi, ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu.