Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fojú di aláṣẹ ń tàpá sí àṣẹ Ọlọrun. Àwọn tí ó bá sì ṣe àfojúdi yóo forí ara wọn gba ìdájọ́. Nítorí àwọn aláṣẹ kò wà láti máa dẹ́rù ba àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn oníṣẹ́ ibi ni ó ń bẹ̀rù àwọn aláṣẹ. Ṣé o kò fẹ́ kí òfin máa já ọ láyà? Máa ṣe ohun rere, o óo sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣòfin. Nítorí iṣẹ́ Oluwa ni àwọn aṣòfin ń ṣe fún rere rẹ. Ṣugbọn bí o bá ń ṣe nǹkan burúkú, o jẹ́ bẹ̀rù! Nítorí kì í ṣe lásán ni idà tí ó wà lọ́wọ́ wọn. Ọlọrun ni ó gbà wọ́n sí iṣẹ́ láti fi ibinu gbẹ̀san lára àwọn tí ó bá ń ṣe nǹkan burúkú. Nítorí náà, eniyan níláti foríbalẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀rù ibinu Ọlọrun nìkan, ṣugbọn nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wa pàápàá sọ fún wa pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ìdí kan náà nìyí tí ẹ fi ń san owó-orí. Iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn aláṣẹ ń ṣe, nǹkankan náà tí wọ́n tẹra mọ́ nìyí. Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ. Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkohun, àfi gbèsè ìfẹ́ tí ẹ jẹ ara yín. Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ràn ẹnìkejì ti pa gbogbo òfin mọ́. “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin. Ìfẹ́ kò jẹ́ ṣe nǹkan burúkú sí ẹnìkejì. Nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin. Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́.
Kà ROMU 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 13:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò