Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un. Nítorí bí a ti ní ẹ̀yà ara pupọ ninu ara kan, tí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara wọnyi kì í sìí ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀. Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ. Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é.
Kà ROMU 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 12:3-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò