Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan. Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.” Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú.
Kà ROMU 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 12:17-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò