ROMU 12:16-21

ROMU 12:16-21 YCE

Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín. Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere. Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan. Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.” Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú.