Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.”
Kà ROMU 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 10:8-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò