ÌFIHÀN 7:11-12

ÌFIHÀN 7:11-12 YCE

Gbogbo àwọn angẹli tí ó dúró yí ìtẹ́ náà ká, ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun ati àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ń wí pé, “Amin! Ìyìn, ògo, ọgbọ́n, ọpẹ́, ọlá, agbára ati ipá ni fún Ọlọrun wa lae ati laelae. Amin!”