ÌFIHÀN 6:1-6

ÌFIHÀN 6:1-6 YCE

Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!” Mo bá rí ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ọrun ati ọfà lọ́wọ́. A fún un ní adé kan, ó bá jáde lọ bí aṣẹ́gun, ó ń ṣẹgun bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó tú èdìdì keji, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè keji ní, “Wá!” Ni ẹṣin mìíràn bá yọ jáde, òun pupa. A fi agbára fún ẹni tí ó gùn ún láti mú alaafia kúrò ní ayé, kí àwọn eniyan máa pa ara wọn. A wá fún un ní idà kan tí ó tóbi. Nígbà tí ó tú èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta ní, “Wá!” Mo rí ẹṣin dúdú kan. Ẹni tí ó gùn ún mú ìwọ̀n kan lọ́wọ́. Mo wá gbọ́ nǹkankan tí ó dàbí ohùn láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà, ó ní, “Páànù ọkà bàbà kan fún owó fadaka kan. Páànù ọkà baali mẹta fún owó fadaka kan. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan igi olifi ati ọtí waini.”