ÌFIHÀN 19:6-21

ÌFIHÀN 19:6-21 YCE

Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba. Ẹ jẹ́ kí á yọ̀, kí inú wa dùn, ẹ jẹ́ kí á fi ògo fún un, nítorí ó tó àkókò igbeyawo Ọ̀dọ́ Aguntan náà. Iyawo rẹ̀ sì ti ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ dè é. A fún un ní aṣọ funfun tí ń dán, tí ó sì mọ́. Aṣọ funfun náà ni iṣẹ́ òdodo àwọn eniyan Ọlọrun.” Ó sọ fún mi pé, “Kọ ọ́ sílẹ̀: àwọn tí a pè sí àsè igbeyawo ti Ọ̀dọ́ Aguntan náà ṣe oríire.” Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ọ̀rọ̀ wọnyi.” Ni mo bá dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, mo júbà rẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ bí ìwọ ati àwọn arakunrin rẹ, tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu, ni èmi náà. Ọlọrun ni kí o júbà.” Nítorí ẹ̀mí tí ó mú kí eniyan jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu ni ẹ̀mí tí ó wà ninu wolii. Mo rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀. Mo wá rí ẹṣin funfun kan. Orúkọ ẹni tí ó gùn ún ni Olódodo ati Olóòótọ́, nítorí pẹlu òdodo ni ó ń ṣe ìdájọ́, tí ó sì ń jagun. Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná. Ó dé adé pupọ tí a kọ orúkọ sí, orúkọ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀ àfi òun alára. Ó wọ ẹ̀wù tí a rẹ sinu ẹ̀jẹ̀. Orúkọ tí à ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ogun ọ̀run ń tẹ̀lé e, wọ́n gun ẹṣin funfun. Aṣọ tí wọ́n wọ̀ funfun, ó sì mọ́. Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare. A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.” Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun, kí ẹ lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba ati ti àwọn ọ̀gágun, ati ti àwọn alágbára, ati ẹran ẹṣin ati ti àwọn tí wọ́n gùn wọ́n, ati ẹran-ara àwọn òmìnira ati ti ẹrú, ti àwọn mẹ̀kúnnù ati ti àwọn ọlọ́lá.” Mo wá rí ẹranko náà ati àwọn ọba ilé ayé ati àwọn ọmọ-ogun wọn. Wọ́n péjọ láti bá ẹni tí ó gun ẹṣin funfun náà ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jagun. A mú ẹranko náà lẹ́rú, pẹlu wolii èké tí ó ń ṣe iṣẹ́ abàmì níwájú rẹ̀, tí ó ti tan àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko náà jẹ, ati àwọn tí wọ́n júbà ère rẹ̀. A wá gbé àwọn mejeeji láàyè, a sọ wọ́n sinu adágún iná tí a fi imí-ọjọ́ dá. Wọ́n fi idà tí ó wà lẹ́nu ẹni tí ó gun ẹṣin funfun pa àwọn yòókù. Gbogbo àwọn ẹyẹ bá ń jẹ ẹran-ara wọn ní àjẹrankùn.